Revelation of John 18:9-10

9 a“Àti àwọn ọba ayé, tí ó ti ń bá a ṣe àgbèrè, tiwọn sì ń hùwà wọ̀bìà, yóò sì pohùnréré ẹkún lé e lórí, nígbà tí wọn bá wo èéfín ìjóná rẹ̀. 10Wọ́n ó dúró ní òkèrè réré nítorí ìbẹ̀rù iṣẹ́ oró rẹ̀, wọn ó máa wí pé:

“ ‘Ègbé! Ègbé, ni fún ìlú ńlá náà,
Babeli ìlú alágbára nì!
Nítorí ní wákàtí kan ni ìdájọ́ rẹ dé!’
Copyright information for YorBMYO